QUICK CONTACT
WHATSAPP PHONE CALL

Oriki Modakeke Akoraye

Filed Under: Talk Zone

On: November 26, 2005


Omo Ogunteludo
Omo Akin loju ogun
Omo Ogunsuwapo ni Modakeke Ile
Omo a to ija gbo de
Bi ija ko ba si mo, n o lo te ilu idakeje do
Maa wa wo baba eni t o maa to mi
Eni ti n mi kukute, ara re ni mi
Omo orori i baba eni ni aa ku si
Omo Eye Ako ori Araba ti n fohun bi eniyan ni Modakeke Ile
Omo Ako ma ba mi ja, n ko se ‘ibi
Omo eni ba se ibi ni eye i yo l’oju je
Omo Eye gbe mi, n ko se ibi
Omo Ako gbe mi, n ko da ‘le
Omo eni eye ba gbe ni l’owo
Omo eni Ako bag be nii de lorun ni Modakeke Ile
Omo afedejinle ba eye igbe soro
Baa mede Ako, bi obo ni aa ri
E je ki a kuku korin ti eye ni a maa ko
Omo a dake ja bi Esu Odara
‘Beeni Akoraye ko b’enikan s’ota
Eni ti o ba to Eye ni Eye I yo l’oju je
Omo Akoraye ko roju iregbe
Bi Modakeke ba ti ji, ibi ise re ni ilo
Omo Ogbagba tii gba ara adugbo
O gba ara ile, o gba ara oko
O gba ero ona tin lo si ajo
Omo Oyigbiriyigbiri
Omo a bi oogun yi gbirigbiri laja
Omo Oba l’ode Oyo
Omo Atata ‘kunrin
Omo gba mi, gba mi, ko ye agba
Omo gba mi, gba mi ko ye omo Akin
Omo a to f’ija gbo de
Omo matanmi, n ko tan ara mi
Omo eni tan ara re lo d’arinna ko
Omo bi o ba baaje, uno ba o baa je
Omo bi o ba tun se, ki n ba o tun se
Omo Eegun
Omo Oro
Omo Oro Epe
Omo orisa pataki mesan ti nbe l’Oyo Ile
Omo eran fifun oke Ipao ti a ko gbodo f’oju di
Omo akanti Oke Ipao
Omo a r’erin pade ija l’ona
Omo ija ko wu mi ja loja
Omo arenije lo mu mi fa orun yo
Omo odo kan ti won n pe l’agbara ni Modakeke Ile
Omo omi teere tii gba agbara lowo asebi
Omo a to fi ija gbo de
Omo Orisa tii gbe ole ko si
Omo ori eni nii gbe ni
Omo enini gbigbon gbe mi
Mo ti ibi oko dida di baba
Omo ori mi gbe mi
Ako gbe mi
Orisa oke gbe mi

 

Please follow and like us:
CLICK TO DROP YOUR COMMENT


CHECK THE MUSIC OUT


Comment Below:-

Enter Name Below (Optional)

(Required)


Enter Comment Below